DOWNLOAD FREE MP3
GOSPELMINDS TELEGRAM

MUSIC + LYRICS:: Tope Alabi – Oruko Tuntun

Tope Alabi - Oruko Tuntun
Gospel Songs Mp3

Check out this Tope Alabi Songs titled “Oruko Tuntun” meaning (New Name). One of the tracks, which is is also the title of the album explains the power in the names we call ourselves and the need for a new and positive one.

Oruko Titun is indeed a song that would minister to you personally.

DOWNLOAD MP3 9.9 MB

LYRICS: Oruko Tuntun By Tope Alabi.

Olorun to da mi w’aye o, lo ni oruko mi amutorunwa

Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko

Emi lologo alayanmo ire, mo w’aye wa f’ogo

Olorun han

Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan

Olorun to da mi w’aye o, lo ni oruko mi amutorunwa

Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko

Emi lologo alayanmo ire, mo w’aye wa f’ogo Olorun han Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan

Eto Olorun ni emi je Aseda f’inu f’edo f’ife da mi O mo mi ni iri Ohun gangan

Mi o ku si’bi kan, O da mi daradara Emi lamo t’owo Adaniwaye mo Eemi Aseda ni iwalaaye mi Oju ogo Re ni iriiran mi akoko Ipa lo fi se mi s’inu iya mi Ara nla owo Oga ogo ni mi Emi leniyan Olorun to da mi w’aye o, lo ni oruko mi amutorunwa

Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko Emi lologo alayanmo ire, mo w’aye wa f’ogo Olorun han Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan Irin ajo eda wa s’aye, esu, ota, elenini eniyan n duro Ami ibi to tele eda bo ni satani t’a le sokale lat’orun O n bu ramuramu, o n kanra, lo fi n fi’bi han eda leemo Eni ba w’aye (w’aye) Eeyan to n gb’aye (gb’aye) E ma sai bikita p’aye kun fun ibi Olorun to da wa, ko da wa tori ibi Olorun to da mi w’aye o, lo ni oruko mi amutorunwa Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko Emi lologo alayanmo ire, mo w’aye wa f’ogo Olorun han Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan

Ti Oluwa ni ile, ati ekun re Ohun gbogbo to da s’oke eepe lo dara Satani lo so won d’ibi Eniyan e ma se ran lowo Ma je k’an f’ibi so e loruko, ire ni’wo je o ma gbagbe Oruko a maa ro ni Jowo ma se bi alaigbon Ohun t’aa ba n je la o da Ara e gb’oruko t’awon eeyan n pe ‘ra won (oruko t’on n pe ‘ra won) E gb’oruko t’eniyan n pe ‘ra re (e gb’oruko t’on n pe ‘ra won) Oloriburuku, talaka n’on n pe ‘ra won (oruko t’on n pe ‘ra won) Agan, were, alaarun ni won n pe ‘ra won (e gb’oruko t’on n pe ‘ra won) Omugo, didinrin ni won n pe ‘ra won (oruko t’on n pe ‘ra won) Alayebaje, atoole n’on n pe ‘ra won (e gb’oruko t’on n pe ‘ra won) Aletilapa ni won n p’omo won (oruko t’on n pe ‘ra won) Ah e o mo p’ohun t’a ba pe loruko o lagbara lori eda Ohun ti o n la koja ooo, jowo ma fi pe ‘ra e mo Enikeni to ni ‘dojuko isese kan, e ma fi pe loruko Ma f’epe san epe, maa ko oruko buburu, satani lo n je baun A ti d’ele aye na, dandan ni k’a laagun k’a to yo, sise pelu ero ire, wa a yo Awon elomiran a ni nile awon bi won o logun odun ni’gbeyawo won o ni le bimo Won a ni nile won (won kii le ko’le) Won a ni nile awon (won kii gbo k’on to ku) Idojuko won (n’on fi n pe ‘ra won) A ni aisan to n se ohun (n lo pa ‘ya ohun) Won a tun fun loruko (alaarun idile) Won a lohun gangan (logun ebi won) Eda n f’oruko isoro (p’oriki ara re) Won a ni b’o ti n se won (n’ile awon niyen) Eda e so’ro to dara jade, ero alaafia lOlorun ni si wa Ma f’ogun enu se ‘ra e pa Pe ‘ra e ni hun to fe je Oruko to dara lOlorun so mi Oruko to logo o lEleda n pe mi Oruko to dara ni emi n je Aseda mo mi ire Emi ako’rewaye Emi agb’ayesayo Mi o ya’gan lona kankan Aisiki ola, wura oro, ara owo Aseda, lemi eniyan Igbagbo n se pupo loro eda (alaisan ti o ni ‘gbagbo ko le gba ‘wosan) Ireti logun f’oruko tuntun (alainireti ko le kuro loju kan) Eda segun nipa oro enu re (iku ati iye wa lori ahon) Ma s’ahon d’ida fi sa ara e si wewe (wa a jere ohun to ba f’enu so) Eni to da’na s’aaro ti o gbe ‘hun le’na (o daju ko ni ‘hun se) O kan fe ya’na lasan ni, igbagbo ni yo ba ero e sise Ja ijangbara fun oruko rere, oruko lo n ro ni Oruko to dara lOlorun so mi Oruko to logo o lEleda n pe mi Oruko to dara ni emi n je Aseda mo mi ire Emi ako’rewaye Emi agb’ayesayo Mi o ya’gan lona kankan Aisiki ola, wura oro, ara owo Aseda, lemi eniyan Eda to n gbe ‘nu aye, yara pada s’odo Aseda On lo mo’di oro, On lo le yanju e F’Adaniwaye se edidi aye re, mura lati s’atunse gbogbo Ko lati je oruko t’aye n so ni, to n ba ayanmo wo ‘jakadi Ore b’Olorun d’owo po o, k’aye e ko le toro Ore b’Olorun laja, ko le j’oruko tuntun Oruko to dara lOlorun so mi Oruko to logo o lEleda n pe mi Oruko to dara ni emi n je Aseda mo mi ire Emi ako’rewaye Emi agb’ayesayo Mi o ya’gan lona kankan Aisiki ola, wura oro, ara owo Aseda, lemi eniyan Obedi-Edomu j’oruko tuntun (o j’oruko tuntun) Bartholomew j’oruko tuntun (o je oruko tuntun) Jakobu j’oruko tuntun (o j’oruko tuntun) Dafidi j’oruko tuntun (o je oruko tuntun) Maria Magdaleni j’oruko tuntun (o j’oruko tuntun) Soolu j’oruko tuntun (o je oruko tuntun) Peteru apeja j’oruko tuntun ooo (o j’oruko tuntun) At’emi nipa eje odo aguntan, mo gba ire, to je ini mi pada Olorun to da mi w’aye o, lo ni oruko mi amutorunwa Eleda to da mi leniyan lo so mi loruko akoko Emi lologo alayanmo ire, mo w’aye wa f’ogo Olorun han Aisiki ire, sabaabi idunnu lemi eniyan Emi t’a da (Emi t’a da) Laworan Olorun (Olorun) Emi eda (Emi eda) Mo ri ojurere (Ojurere) Mo loore ofe to ga julo Emi lori (Emi lori) Mi kii se iru o (Lailai) Emi t’a da (Emi t’a da) T’ewa t’ogo Olorun (Olorun) Lat’odo Aseda o, ola mi o lakawe A ti fi oruko tuntun pe mi, emi A ti fi oruko tuntun pe mi, Amin A ti fi oruko tuntun pe mi, emi A ti fi oruko tuntun pe mi, Amin A ti fi oruko tuntun pe mi, emi A ti fi oruko tuntun pe mi, Amin

Twitter | Instagram | Facebook@Gospelminds_com

Leave a Reply